Wọlé Sóyinká

Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
(Àtúnjúwe láti Wole Soyinka)

Akínwándé Olúwọlé Babátúndé Ṣóyínká (ọjọ́ìbí 13 July 1934) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) nínú Ìmọ̀ Lítíréṣọ̀ (literature), alákọsílẹ̀, eré orí ìtàgé (playwright) àti akéwì (poet). Wọlé Sóyinká jẹ́ ògidì ọmọ Yorùbá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gba Ẹ̀bùn Nobel ní ọdún 1986 fún iṣẹ́ ọwọ́ ọ rẹ̀ lórí i ìgbéga ìmọ̀ ìkọ̀wé.[2].

Wọlé Sóyinká
Wọlé Sóyínká ní 2018
Ọjọ́ ìbíAkínwándé Olúwolé Babátúndé Sóyíinká[1]
13 Oṣù Keje 1934 (1934-07-13) (ọmọ ọdún 90)
Abeokuta, Nigeria Protectorate (now Ogun State, Nigeria)
Iṣẹ́
  • Òǹkọ̀wé
  • Akọ-ewì
  • Akọ-eré
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́Abeokuta Grammar School
University of Leeds
Ìgbà1957–present
Genre
  • Drama
  • novel
  • poetry
SubjectComparative literature
Notable awardsNobel Prize in Literature
1986
Academy of Achievement Golden Plate Award
2009

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

Wọ́n bí Wọlé Sóyinká ní ìlú Abẹ́òkúta, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà àti United Kingdom tán, Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Theatre Royal Court ni ìlú Loọ́ńdọ̀nù (London). Ó tẹ̀ síwájú láti kọ àwọn eré oníṣe lorílẹ̀ èdè méjèèjì ní tíátà àti orí ẹ̀rọ Asọ̀rọ̀-mágbèsì. Ó kó ipa pàtàkì nínú ètò ìṣèlú àti akitiyan lópọ̀lọpọ̀ nínú ìjàǹgbara òmìnira orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn Great Britain.[3]

Wole Soyinka de ko ere ti won te ni Nàìjíríà ati oke okun ,ire itagbe ati ire olori redio.Wole je eniyan paataki ninu ija ominira Naijira lati owo awon Ilu Oba.

Àwọn Ìtọ́kasí

4. Open Country Magazine. https://opencountrymag.com/52-books-in-64-years-your-guide-to-all-work-by-wole-soyinka/