Sódíọ̀mù jẹ́ ẹ́límẹ̀ntì kẹ́míkà kan tó ní àmí-ìdámọ̀ Na (láti Látìnì: natrium) lórí tábìlì ìdásìkò àwọn ẹ́límẹ̀ntì àti nọ́mbà átọ̀mù 11. O je metali riro, alawo fadaka funfun to untete sedarapo, beesini o je ikan ninu awon metali alkali; Isotopu re nikan to fesemule ni 23Na. Metali yi ko da wa fun ra ara re nikan ni idaye, sugbon be o wa ni adapo; o koko je pipinsoto latowo Humphry Davy ni 1807 pelu elektrolisisi haidroksidi sodiumu. Sodiomu ni elimenti ikefa to gbale julo ninu ipele-igbele Aye, o si wa ninu opo awon alumoni bi feldspar, sodalaiti ati iyo okuta. Opo awon iyo sodiomu ni won je yiyo somi daada, be sini sodiomu won ti je yiyo jade latowo omi to fi je pe kloridi ati sodiomu ni awon elimenti to wopo ni wuwo ninu awon omi okun Ile-Aye.