SARS-CoV-2

Kòkòrò èràn àrọ́lù àìsàn ìmín olóró gbígboró, èrànkòrónà irú 2 tó gbajúmọ̀ pẹ̀lú orúkọ sáyẹ́nsì rẹ̀ SARS-CoV-2 (Severe acute respiratory syndrome coronavirus 2)[2] tàbí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ bíi èrànkòrónà Wuhan[3] tàbí èrànkòrónà tuntun 2019 (2019 novel coronavirus, 2019-nCoV)[4][5] jẹ́ èrànkòrónà kan pẹ̀lú èròjà àbímọ́ RNA adáraṣe pẹ̀lú ẹnu-igun apọ̀si

Severe acute respiratory syndrome coronavirus 2
Electron micrograph of SARS-CoV-2 virions with visible coronae
Transmission electron micrograph of SARS-CoV-2 virions with visible coronae
Illustration of a SARS-CoV-2 virion
Illustration of a SARS-CoV-2 virion[1]
Ìṣètò ẹ̀ràn [ e ]
(unranked):Èràn
Realm:Riboviria
Ará:Incertae sedis
Ìtò:Nidovirales
Ìdílé:Coronaviridae
Ìbátan:Betacoronavirus
Subgenus:Severe acute respiratory syndrome-related coronavirus
Irú:
Severe acute respiratory syndrome-related coronavirus
Irú-ìdá:
Severe acute respiratory syndrome coronavirus 2
Synonyms
  • 2019-nCoV

Kòkòrò èràn yìí ni ó fa àrùn COVID-19, tó jẹ̀ àrùn alákòóràn láàrin àwọn ènìyàn. Kò sí ògùn ìbupánaunba fún kòkòrò èràn yìí. Nítoríẹ̀ Àjọ Ilèra Àgbáyé ti pe àjákálẹ̀ àrùn COVID-19 tó ún lọ lọ́wọ́ ní Pàjáwìrì Ilera Ìgboro tó kan gbogbo Ayé[6][7][8].

Ìtò sí àyè rẹ̀ fi hàn pè, SARS-CoV-2 jẹ́ irú kòkòrò àrọ́lù àìsàn ìmín olóró gbígboró tó jẹ mọ́ erànkòrónà (SARSr-CoV). Ìgbágbọ́ ni pé ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko ló ti wá nítorí pé ó ní ìjọra mọ́ àwọn kòkòrò èrànkòrónà àdán[9][10][11][12].

Àwọn ìwádìí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ àjàkálẹ̀-àrùn díye pé ẹni tó bá ní kòkòrò èràn yìí le kóoran àwọn elòmíràn tuntun tótó 1.4 sí 3.9 tí ẹnìkankan láwùjọ kó bá ní àjẹsára àti tí kó sì sí ètò ìjánu àrùn kankan. Kòkòrò èràn yìí ún ràn ká nípa fífara kan ara àti nípa wíwúkọ́ tàbí sísín.[13][14] Ó ún wọ nú ìhámọ́ ara ènìyàn nípa síso mọ́ angiotensin converting enzyme 2 (ACE2).[9][15][16]

Ọrúkọ

The name "2019-nCoV" in use in a trilingual sign at a Lisbon health facility in February 2020.

Nígbàtí ìjálẹ̀ àrùn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ilú Wuhan ní Ṣáínà, orúkọ tí wọ́n sábà pe kòkòrò èràn náà nígbà náà ni "èrànkòrònà (coronavirus)", "èrànkòrònà Wuhan (Wuhan coronavirus)",[17][18][19] tàbí "èràn Wuhan (Wuhan virus)".[20][21] Ní January ọdún 2020, Àjọ Ìlera Àgbáyé dáàbá orúkọ "èrànkòrónà tuntun ọdún 2019 (2019 novel coronavirus)" (2019-nCov)[22][23] fún kòkòrò èràn náà. Èyí ní ìbámu mọ́ ìlànà AIA (WHO) ọdún 2015[24] tó lòdì sí lílo orúkọ ibùgbé (f.a. Wuhan), orúkọ irú ẹranko, tàbí orúkọ ẹ̀yà ènìyàn fún orúkọ àrùn tàbí kòkòrò èràn.[25][26] Ní 11 February 2020, ìgbìmọ̀ International Committee on Taxonomy of Viruses (Ìgbìmọ̀ Àgbáyé lórí Ìpínsíàyè àwọn Kòkòrò Èràn) gba orúkọ yìí "àrọ́lù àìsàn ìmín olóró gbígboró, èrànkòrónà irú 2" (severe acute respiratory syndrome coronavirus 2; SARS-CoV-2) gẹ́gẹ́ bíi orúkọ àlòsiṣẹ́.[27] Láti mọ́ baà ṣe àsìṣe rẹ̀ m àrùn SARS, Àjọ Ìlera Àgbáyé nígbà míràn le pe SARS-CoV-2 bi "the COVID-19 virus" (èràn COVID-19) nínú àwọn ìkéde wọn.[28][29] Àwọn míràn tún pe SARS-CoV-2 àti àrùn rẹ̀ bíi "àrùn kòrónà" tàbí "kòkòrò kòrónà".

Ìmọ̀ kòkòrò èràn

Ìtọ́kasí