Lupita Nyong'o
Lupita Amondi Nyong'o (US /luːˈpiːtə ˈnjɔːŋoʊ/,(ọjọ́ìbí :ọjọ́ kini oṣù kẹta ọdún 1983) jẹ́ òṣèré sinimá ará ilẹ̀ Kẹ́nyà, ṣùgbọ́n tí wọ́n bí ní orílè-èdè Mexico. Ó kọ́kọ́ kópa nínú fíìmù kan lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bí Patsey eyi tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ 12 Years a Slave tí Steve McQueen darí lọ́dún 2013.[2] [3]. Ó lọ sí kọ́lẹ̀jì ní Amẹ́ríkà, ó sì gba òye nínu fíìmù àti àwọn ẹkọ tíátà ní Hampshire College .
Lupita Nyong'o | |
---|---|
![]() Nyong'o in 2019 | |
Ọjọ́ìbí | Lupita Amondi Nyong'o[1] 1 Oṣù Kẹta 1983 Mexico City, Mexico |
Ibùgbé | Brooklyn, New York, U.S. |
Ọmọ orílẹ̀-èdè |
|
Ẹ̀kọ́ | Hampshire College (BA) Yale University(MFA) |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2005–present |
Parents |
|
Àwọn olùbátan | Isis Nyong'o Tavia Nyong'o |
Awards | Full list |
Nyong'o bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní Hollywood bí olùrànlọ́wọ́ Olùpìlẹ̀ṣẹ̀ fíìmù. Ní ọdún 2008, ó ṣe ìṣà fihàn òṣèré àkọ́kọ́ pẹ̀lú fíìmù kúkúrú ti East River [4]àti lẹhin náà ó padà sí Kenya láti ṣe ìràwọ̀ ní fíìmù tẹlifíṣọ̀nù Shuga (2009–2012)[5]. Pàápàá ní ọdún 2009, ó kọ̀wé , ó sì ṣe àgbékalẹ̀ àti ìtọ́sọ́nà ìwé ìtàn In my genes[6]. Lẹ́hìn náà ó lépa àléfà oyé ní ṣíṣe eré ní Yale School of Drama . Láìpẹ́ lẹ́hìn ayẹyẹ ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀ , ó ní ipa fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ bí Patsey nínú eré ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ti Steve McQueen 12 Years a Slave (2013), [7]fún èyítí ó gba ìyìn pàtàkì àti gba ọpọlọpọ awọn aami-ẹri, nínú rẹ̀ ni Academy Award for Best Supporting Actress Ó di arábìnrin àkọ́kọ́ ti Ìlú Kenya àti ará ìlú Mexico láti gba Academy Award[8]