John Lewis
John Robert Lewis (Oṣù Èrèré 21, 1940 – Oṣù Agẹmọ 17, 2020) jẹ́ olósèlù ọmọ orílẹ̀-èdè America, àti ajìjà gbara tí ó jẹ́ asojú ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Goeorgia láti ọdún 1987 sí ọdún 2020 tí ó fi di olóògbé[1].
John Lewis | |
---|---|
Member of the U.S. House of Representatives from Georgia's 5th district | |
In office January 3, 1987 – July 17, 2020 | |
Asíwájú | Wyche Fowler |
Arọ́pò | Vacant |
3rd Alága igbimọ akékọ̀ álá'laafià | |
In office June 1963 – May 1966 | |
Asíwájú | Charles McDew |
Arọ́pò | Kwame Ture |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | John Robert Lewis Oṣù Kejì 21, 1940 Troy, Alabama, U.S. |
Aláìsí | July 17, 2020 Atlanta, Georgia, U.S. | (ọmọ ọdún 80)
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Democratic |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Lillian Miles (m. 1968; died 2012) |
Àwọn ọmọ | John-Miles Lewis |
Education | American Baptist College (BA) Fisk University (BA) |
Website | House website |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Ẹ̀gbẹ́ Troy, Alabama ni wọ́n bí John Robert Lewis sí ní oṣù Èrèré 21, 1940. Òun ni ọmọ kẹ́ta nínú ọmọ mẹ́wàá tí Willie Mae àti Eddie Lewis bí.[2][3][4] Àgbẹ̀ ayálégbé tí ó máa ń fi erè oko rẹ̀ sanwó ilé ní àwọn òbí John ní abulé Pike County, Alabama, èyí tí Troy jẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀.[5][6].
lGẹ́gẹ́ bí ọmọdé, wu Lewis láti jẹ́ oníwàásù.[7] Ní ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún márùn-ún ní ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní máa wàásù fuh àwọn edìyẹ tó wà ní oko wọn.[8] Lewis ní àǹfàní àti bá wọn aláwọ̀ funfun sọ̀rọ̀ nígbà tí ó wà ní kékeré, nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́fà, aláwọ̀ funfun méjì péré níkàn ló ti bá sọ̀rọ̀. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn aláwọ̀ dúdú ni ó pọ̀ jù ní ibi tí wọ́n ń gbé, àgbẹ̀ sì ni àwọn ebí rẹ̀.[9] Ó ṣe àpèjúwe ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlé-ìwé kékeré tí kò jìnà sí ilé òun. Rosenwald School ni orúkọ ilé-ìwé ọ̀hún, ìlé-ìwé yìí nìkan ni ilé-ìwé tí wọ́n ní agbègbè wọ́n.[10]
Itokasi
S