Grace Oladunni Taylor
Grace Oladunni Taylor (tí a tún mọ̀ sí Grace Oladunni Lucia Olaniyan-Taylor; tí a bí ní ọjọ́ 24 oṣù kẹrin, ọdún 1937)[1] jẹ́ biochemist, ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn nígbà kan rí. Òun ni obìnrin ẹlẹ́ẹ̀kejì tí wọ́n máa gbà wọlé sí Nigerian Academy of Science àti obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ láti gba àmì-ẹ̀yẹ̀ L'Oréal-UNESCO Award for Women in Science.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
Ìlú Efon-Alaiye, ní ipinle Ekiti,ni a bí Grace Oladunni Lucia Olaniyan sí, sínú ìdílé Elizabeth (née Olatoun) àti R. A. W. Olaniyan. Láàárín ọdún 1952 àti 1956, ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwé Queen's School ní Ede ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.Ó forúkọ wọlé sí ilé-ìwé gíga ní ọdún 1957 ní Nigerian College of Arts and Science ní Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu, ní ọdún 1959, wọ́n gbe lọ sí Yunifásitì College of Ibadan (tí ó wá di Yunifásítì ìlú Ìbàdàn báyìí). Olaniyan kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pẹ̀lú èsì tó dá ní ọdún 1962, pẹ̀lú ìwé-ẹ̀rí nínú ẹ̀kọ́ chemistry.[2]