Gideon Okeke

Gideon Okeke jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán.[1][2][3] Ó di gbajúmọ̀ ní ọdún 2006, nígbà tí ó kópa nínú ìdíje ti Big Brother Nigeria. Ní ọdún 2008, Gideon dara pọ̀ mọ́ àwọn akópa ti fíìmù M-NET tí wọ́n máa ń ṣàfihàn lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, ìyẹn Tinsel.[4]

Gideon Okeke
Gideon Okeke at the 2021 AMA Awards
Ẹ̀kọ́Biochemistry, Nnamdi Azikiwe University
Iléẹ̀kọ́ gígaNnamdi Azikiwe University
Iṣẹ́Actor, Model, and TV Presenter.
Ìgbà iṣẹ́2006–present
Notable workRelentless
TelevisionBig Brother Nigeria
Tinsel
Àwọn ọmọ1

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

Gideon jẹ́ ọmọ kan ṣoṣo tí àwọn òbí rè bí, ó sì dàgbà sí Ajegunle, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó kún fún jàgídíjàgan ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[5] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Nnamdi Azikiwe University, níbi tí ó ti kọ́ nípa applied bio-chemistry. Lẹ́yìn náà ni ó forúkọ sílẹ̀ ní Lee Strasberg Institute, ní New York, níbi tí ó ti gba ẹ̀kọ́ nípa eré ṣíṣe.[5]

Iṣẹ́ rẹ̀

Iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

Lẹ́yìn tó farahàn nínú ìdíje Big Brother Nigeria, Gideon darapọ̀ mọ́ àwọn akópa eré Tinsel, èdá-ìtàn Phillip Ade Williams, sì ló ṣe.[6][7] Gideon ti farahàn nínú fíìmù ilẹ̀ South Africa kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jacobs cross.[7] Ní ọdún 2014, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn Bernard nínú fíìmù irokotv kan, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Poisoned Bait, èyí ti Leila Djansi darí. Bákan náà, Gideon ni olóòtú ètò DSTV kan tó ń jẹ́ Money Drop.[8]

Fíìmù

Fíìmù àkọ́kọ́ tí Gideon máa ṣe ní fíìmù Nàìjíríà kan, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Relentless, ní ọdún 2010. Lára àwọn akópa mìíràn tí wọ́n jìjọ ṣe fíìmù náà ni Jimmy Jean-Louis àti Nneka Egbuna.[9] Fíìmù ẹ̀kejì rẹ̀ ni fíìmù ọdún 2014 kan, tó jẹ́ mọ́ ìwá̀-ọ̀daràn, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A Place in the Stars. INí ọdún kan náà, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn Tobena, nínú fíìmù ajẹmọ́fẹ̀ẹ́ kan, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ When Love Happens. Àwọn fíìmù mìíràn tí ó ṣe ni Gbomo Gbomo Express, àti 93 Days.[10][11]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

Eré orí-ìtàgé

YearTitleRoleRef
Fractures
Fela... Arrest the MusicFela
Saro the Musical 2Azeez

Eré orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

YearTitleRole
2007Big Brother NaijaHimself
2008–presentTinselPhillip Ade Williams
Jacob's cross
2014Poisnned Bait
Money DropHost

Fíìmù àgbéléwò

YearTitleRole
2006RelentlessObi
2014A Place in the StarsKim Dakim
...When Love HappensTobena
201693 DaysMorris-Ibeawuchi
Gbomo Gbomo ExpressFrancis
2021Loving RonaBenny Ramsey
2022Obsession (2022 film)

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

YearAwardCategoryWorkResultRef
2022Africa Magic Viewers' Choice AwardsBest Actor in A ComedyLoving Rona Iṣẹ́ ń lọ lórí ẹ̀[12]

Àwọn ìtọ́kasí