Emeka Nwabueze

 

Emeka Nwabueze
BornEmeka Patrick Nwabueze
23 Oṣù Kẹ̀sán 1949 (1949-09-23) (ọmọ ọdún 74)
Umubele village, Awka South LGA, Anambra State
NationalityNigerian
Institutions
  • Kano State Institute for Higher Education,
  • Edward Waters College
  • University of Nigeria, Nsukka
Alma mater
  • University of Nigeria, Nsukka
  • University of Jos
  • Eastern Michigan University
  • Bowling Green State University

Emeka Patrick Nwabueze jẹ́ Ojogbon àgbà (Emeritus) àkọ́kọ́ ti ẹ̀kọ́ Tíátà àti Fíìmù ti University of Nigeria, Nsukka . Ó tún fìgbàkanrí jẹ́ gíwá ti Faculty of Arts àti adarí ti ẹ̀kọ́ Afirika tẹ́lẹ̀ ti ilé-ẹ̀kọ́ náà.[1][2][3][4][5]

Ìgbésí ayé ìbẹ́rẹ́ àti ẹ̀kọ́

Wọ́n bi Emeka ni ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Kẹsàn-àn, Ọdún 1949, sínú ìdílé Olóyè John Nweke Nwabueze àti Josephine Nwabueze láti ìlú Umubele ní ìjọ̀ba ìbílẹ̀ gúúsù Awka ti ìpínlẹ̀ Anambra . Ó lọ sí ilé-ìwé St. Patrick's School ni Awka láti ọdún (1958–65). Ó tẹ̀síwájú sí ilé-ẹ̀kọ́ girama Zik's College, Onitsha láti (1966-1971) ó sì wọlé sí University of Nigeria, Nsukkaìní 1971. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1975 lati Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Gẹ̀ẹ́sì, pẹ̀lú iṣẹ́ ìṣeré gẹ́gẹ́ bíi àfojúsùn rẹ̀. Ní ọdún 1977, ó gba postgraduate diploma nínu Ìsàkoso Ẹ̀kọ́ àti Ètò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Jos. Lẹ́hìnnáà, ó tẹ̀síwájú sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Eastern Michigan àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Bowling Green State níbití ó ti gba oyè ẹ̀kọ́ kejì àti Doctorate degree bákannáà. [6]

Iṣẹ́ rẹ́

Emeka bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí olùkọ́ni l'ákòkò National Youths Service Corps ní Kano State Institute for Higher Education ní ọdun 1978. L'ákòkò tí ó wà ní ìlú Amẹ́ríkà ní ìparì ọdún 1983, ó jẹ́ Associate Professor àti Alága ti Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá Ènìyàn ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Edward Waters, ilé-ẹ̀kọ́ gíga ọlọ́dún mẹ́rin ní Jacksonville, Florida, U.S.A. Lẹ́hìn ìpè láti ilé ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ àkọ́kọ́ rẹ́, ó padà sí Nàìjíríà ní ọdún 1983 ó sì gbaṣẹ́ gẹ́gẹ́bi Olùkọ́ni kejì (Lecturer II), ó gba ìgbéga sí Olùkọ́ni àkọ́kọ́ ní 1985, ati Olukọni Agba ni 1987 ni igbega si Ojogbon ni 1996 ati emeritus professor ni 2023. [7][8][9]

Ní ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù Karùn-ún, Ọdún 2000, ó se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ “In the Spirit of Thepsis: Theatre Arts and National Integration ” èyítí ó tọpa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ tíátà ni Eester scholarship àti àwọn àwùjọ ìbílẹ̀, ìtànkálẹ̀ tíátà gẹ́gẹ́bíi ìlànà ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Nàìjíríà, ìdàgbàsókè àtìgbàdégbà rẹ̀, àwọn tíọ́rì itankalẹ tíátà, ati gbígbé lárugẹ àwọn ipa tí Theatre ní lóri ìsọ̀kàn orílẹ̀-èdè nínú àwùjọ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bìi ti Nàìjíríà. [10] [11] [12]

Àwọn ìtọ́kasí