Antar Laniyan

Òṣéré orí ìtàgé

Antar Laniyan jẹ́ ògbóǹtarìgì òṣèrékúnrin, aṣàgbéjáde eré àti olùdarí eré ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Antar Laniyan
Ọjọ́ìbíOsogbo, Osun, Nigeria
Ẹ̀kọ́University of Ibadan, BA in theatre arts
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ibadan
Iṣẹ́Film actor and producer
Ìgbà iṣẹ́1981–present
Notable workSango

Ìgbésí ayé rẹ̀

Ìlú Òṣogbo tó jẹ́ olú-ìlú Ọ̀ṣun, ní apá Ìwọ-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà ni wọ́n bí Laniyan sí.[2] Ìlé-ìwé Baptist Secondary School ni ó ti gba ìwé-ẹ̀rí ( WAEC ),[3]Ìpínlẹ̀ Èkó kó tó di pé ó wá lọ sí Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ tíátà.[4]

Iṣé tó yàn láàyò

Laniyan bẹ̀rẹ̀ iṣé eré-ṣíṣe ní ọdún 1981, ẹ̀dá-ìtàn àkọ́kọ́ tó sì kọ́kọ́ ṣe ni ''major general'' nínú fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Everybody wants to know lákòokòtó wà ní Kakaki Art Squad.[5][6] Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bí i Sango, èyí tó jẹ́ fíìmù tí Wale Ogunyemi ṣe, tí Obafemi Lasode sì jẹ́ olùdarí eré náà.[7][8] Òun ní olùdarí tó darí apá kìíní ti fíìmù Super Story, tí Wale Adenuga ṣàgbéjáde ní ọdún 2000, tó sì ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ.[9] Òun sì ló tún darí fíìmù Oh Daughter àti This Life tí Wale Adenuga bákan náà ṣàgbéjáde.[10]

Àṣààyàn àwọn fíìmù rẹ̀

  • Sango (1997)
  • Super Story (episode 1)
  • Kakanfo (2020)
  • Lucifer (2019)

Àwọn ìtọ́kasí