Ajàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Làìbéríà

Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó tàn dé orílẹ̀-èdè Liberia ní àárín oṣù kẹta ọdún 2020.[2]

Ajàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Liberia
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiLiberia
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, China
Index caseMargibi County
Arrival date16 March 2020
(4 years, 2 months, 3 weeks and 6 days)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn1,216 (as of 4 August)[1]
Active cases440 (as of 4 August)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá698 (as of 4 August)
Iye àwọn aláìsí
78 (as of 4 August)
Official website
https://www.facebook.com/pages/category/Government-Organization/National-Public-Health-Institute-of-Liberia-NPHIL-164280647325112/

Bí ó ṣe bérẹ̀

Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kíní ọdún 2020, Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí. [3][4]Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003. Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìtànkálé àrùn COVID-19 ń gbópọn si lójojúmọ́ tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpò ènìyàn lágbáyé[5][6][7][5]

Àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan tí ó ṣẹlẹ̀

Oṣù kẹta ọdún 2020

Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta, ni wọ́n ní akọsílẹ̀ arùn COVID-9 akọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Liberia lára ẹnìkan tí ó jẹ́ oníṣẹ́ ìlera tí ń bọ̀ láti orílẹ̀-èdè Switzerland. [8] Ààrẹ orílẹ̀-èdè Liberia ọ̀gbẹ́ni George Weah fún aláàrẹ̀ náà ní orúkọ kan látàrí ìlòdì sí òfin àyẹ̀wò ní pápákọ̀ òfurufú Roberts International Airport (RIA) ní ìlú Harbel.[9]Àkọsílẹ̀ ẹlẹ́kejì ni wọ́n rí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta, ẹni náà ni ó ti fara kínra pẹ́lú ẹni akọ́kọ́. [10]

Ẹni kẹta tí ó fara kó àrùn COVID-9 jẹ́ ẹni tí ó ń darí ìrìn-àjò bò láti orílẹ̀-èdè kan. Lẹ́yìn tí ẹni kẹ́ta ti fara káṣá tán, ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ó ń rí sí ìlera kéde ètò ìlera pàjáwìrì ní orílẹ̀-èdè Liberia ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta.[11][12]

Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta, orílẹ̀-èdè olómìnira Ivory Coast kéde títi ibodè ilẹ̀ rẹ̀ pa pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Liberia àti orílẹ̀-èdè Guinea léte ati dènà ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9.[13]

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ilé-iṣẹ́ àṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà kó lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kúrò ní orílẹ̀-èdè Liberia.[14]Nígbà tí oṣù kẹta yóò fi parí, àwọn aláàrẹ̀ mẹ́ta yí náà nìkan ni wọ́n ṣì rí tí wọn kò sì rí òmíràn mọ́.[15]

Oṣù kẹrin ọdún 2020

Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin, orílẹ̀-èdè Liberia pàdánù ẹni akọ́kọ́ ní oṣù kẹrin.[16]Ní ọjọ́ Karùún oṣù kẹrin ilé-iṣẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè Germany pẹ́lú àjọṣepọ̀ Europian Union ṣe agbékalẹ̀ ọkọ̀ òfurufú kan tí yóò kó gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè wọn kúrò.[17]Ní ọjọ́ keje oṣù kẹrin, Ààrẹ George Weah yan ìgbìmọ̀ alákòódo tuntun amúṣẹ́ṣe pàjáwìrì fún ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9 lábẹ́ adarí alákòóso olú ìlú Monrovia, ìyẹn Abilékọ Mary Broh.[18][19]P7pọ̀ nínú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni eọ́n jáyà lórí bí Abilékọ Broh yóò ṣe lè darí ìgbìmò amúṣẹ́ṣe náà láì ní ìmò tó peregedé nípa ètò ìlera, amọ́ yíyan sípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ ìgbìmò ọ̀hún ló lọ́wọ́ ajọ ìṣọ̀kan agbàyé nínú, pàá pàá jùlọ ilé-iṣẹ́ tí ó ń rí sí ìlera ní agbáyé.WHO.[20][17]

Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹrin, Ààrẹ George Weah kéde òfin kónílé-ó-gbélé tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kẹwàá tí yóò sì wà ní mímúlò fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.[21] Gbogbo àwọn ilé-ẹ̀kọ́, ilé-ìjọsìn, ilé;ìgbafẹ́ òun ìtura ni wọ́n wà ní títì pa jákè-jádò orílẹ̀-èdè náà.[12] Àjọ elétò ìlera ti Orílẹ̀-èdè Lineria ti ṣe akọsílẹ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tàn lu gúdẹ àìsàn àrùn Kòrónà láti mẹ́rìnlá sí mọ́kanlélọ́gbọ̀n , tí wọ́n sì padánù ẹnìkan péré sí ọwọ́ ikú àìsàn COVID-9. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Liberia ṣòfin Wíwọ ìbòjú ní àkókò àtànkálẹ̀ àrùn kòrónàfún gbogbo ọmọ.orílẹ̀-èdè Liberia, amọ́ wọ́n ní ṣíse òfin náà.ní dan dan rújú.[22] As of that date, 29 confirmed cases were healthcare workers (out of 101 total confirmed cases).[23]Láàrín oṣù yí, wọ́n ti ní akọsílẹ̀ tí ó tó ọgọ́rùún kan ati méjìdínlógójì, tí ó mú iye gbogbo àwọn aláàrẹ̀ COVID-9 lápapọ̀ jẹ́ ọgọ́rùún kan ati mọ́kanlélógójì ènìyàn. Àwọn márùndínláàdọ́ta ni ara wọn ti yá gágá tí wọ́n sì ti padà sí ilé wọn, àwọn mẹ́rìndínlógún ni wón ti papò dà, nígbà tí àwọn àádọ́rin ṣìwà pẹ̀lú àrùn náà. [24]

Oṣù Karùún ọdún 2020

Iye àwọn tí wọ́n ní arùn náà tún lé méje si nínú oṣù Karùún, iye àwọn tí wọ́n ṣaláìsí jẹ́ mọ́kànlá, iye àwọn tí wọ́n rí ìwòsàn gba jẹ́ ọgọ́rùún kan ó lé méjìlá, nígbà tí àwọn mẹ́rìnlélọ́gọ́rún ṣì wà pẹ́lú àìsàn náà níparí oṣù Karùún.[25]

Oṣù Kẹfà ọdún 2020

Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù Kẹfà, Ààrẹ George Weah kéde àfikún òfin kónílé-ó-gbélé sí ọgbọ̀n ọjọ́ dípò ọjọ́ mèẹ̀dógún tó ti wà tẹ́lẹ̀[26]

Nínú oṣù yí, wọ́n tú ní akọsílẹ̀ ènìyàn ọgọ́rùún márùún ó dín ní ẹyọ kan ṣoṣo, tí ó mú kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti ní àrùn Kòrónà jẹ́ ọgọ́rùún méje ó lé láàdórin, àwọn tí wọ́n gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra jẹ́ mẹ́rìndínlógójì, àwọn ènìyàn ọgọ́rùún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélógún ti gba ìwòsàn tí ó sì ku àwọn ọgọ́rùún mẹ́rin àti ogún ènìyàn tí àìsàn yí ṣì wà lára wọn níparí oṣù kẹfà. [27]

Oṣù keje ọdún 2020

Nínú oṣù kẹjọ, wọ́n tún ní akọsílẹ̀ ènìyàn ọgọ́rin ó lé mẹ́rin ènìyàn tí ó fara káṣá àrùn COVID-9, àwọn tí wọ́n ṣaláìsí jẹ́ márùndínláàdọ́jọ, iye àwọn tí ara wọn yá gágá lé kún sí ọgọ́rùún mẹ́fà ati àádóje, nígbà tí àwọn tó kù tí àárẹ̀ náà wà lára wọn jẹ́ ọgọ́rùún mẹ́rin ati mókanlélógójì.[28]

Àwọn ìgbésẹ̀ ìjọba

Orílẹ̀-èdè Liberia jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ayẹ̀wò fún àwọn èrò inú ọkọ̀ òfurufú fún arùn COVID-9.[12]

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta, orílẹ̀-èdè China ṣe ìtọrẹ àánú nípa fífún ìjọba orílẹ̀-èdè Liberia ní àwọn irinṣẹ́ ìlera lórisirísi.[29]

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin àjọ tí ó ń rí sí okòwò lágbaáyé forí owó tùlù tulu kan tí wọn kò sọ iye tí jẹ́ jin orílẹ̀-èdè náà. [30]oríṣiríṣi àríwísí ni ó ti ń jà ràn-ìn ràn-ìn bóyá kí wọ́n ma dárúkọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ní arùn Kòrónà fáráyé gbọ́, amọ́ ìpinnu ilé-iṣẹ́ ètò ìlera àgbà fún.orílẹ̀-èdè Liberia ni wípé àwọn kò ní orúkọ ẹnikẹ́ni léde wípé ó ní àrùn COVID-9. Ṣùgbọ́n, wọ́n ní láti fi orúkọ àwọn adarí ìjọba bí Ààrẹ ati àwọn.mìíra léde kí èyí lè jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹnikẹ́ni tó bá ní àrùn COVID-9 wípé kìí ṣe òpin ayé àti wípé bí wọn kò bá yọjú, ó léwu fún wọn púpọ̀.[31]

Ẹ tún lè wo

Àwọn ìtọ́kasí

Àdàkọ:COVID-19 pandemic