Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Guinea

Wọ́n kéde àrùn ẹ̀rànkòrónà, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Covid-19 lórílẹ̀-èdè Guinea lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 2020.[3]

Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Guinea
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiGuinea
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, China
Index caseConakry
Arrival dateỌjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 2020
(4 years, 2 months, 4 weeks and 2 days)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn6,544 (as of 19 July)[1][2]
Active cases996 (títí di ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù keje)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá5,511 (títí di ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù keje)[2]
Iye àwọn aláìsí
39 (títí di ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje)[2]
Official website
http://www.anss-guinee.org/

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀

Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni àjọ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) jẹ́rìí pé ẹ̀rànkòrónà, Covid-19, ni ó ń fa àìsàn èémí láàárín àwọn ènìyàn kan lágbègbè Wuhan,ní Ìpínlẹ̀ Hubei, lórílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ̀ fún àjọ WHO lọ́jọ́ kokànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019.[4][5]

Iye ìjàm̀bá ikú àrùn Covid-19 kéré sí ti àrùn SARS, Severe acute respiratory syndrome tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 2003,[6][7] ṣùgbọ́n jíjàkálẹ̀ àrùn náà lágbára ju SARS lọ, pàápàá jù lọ iye àwọn ènìyàn tí àrùn náà ń pa lápapọ̀..[8][6]

Bí ó ṣe ń jàkáalẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà

Ààrẹ Alpha Condé ṣe ìpàdé pẹ̀lú aṣojú orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sí Guinea, Simon Henshaw láti jíróró lórí àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19, níbi tí wọ́n ti ṣe àmúlò Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ.

March 2020

Lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 2020 èsì àyẹ̀wò fihàn pé arákùnrin kan, ọmọ orílẹ̀ èdè Belgium, tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ European Union, tí ó wá ṣe àbẹ́wò lórílẹ̀-èdè Guinea ní àrùn Covid-19. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó ní àrùn náà ni lórílẹ̀-èdè náà.[9][10]

Nígbà tí ó yá, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn náà pọ̀ sí ní ìlọ́po méjì láti mẹ́jọ sí mẹ́rìndínlógún lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2020.[11]

Oṣù karùn-ún

Ìṣẹ̀lẹ̀ láabí kan ṣẹlẹ̀ lóṣù karùn-ún ní Guinea, àwọn ọlọ́pàá pa àwọn mẹ́fà nínú àwọn afẹ̀hónúhàn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ìgbòkègbodò ọkọ̀ ni ìlú Coyah àti Dubreka. Agbẹnusọ àwọn ọlọ́pàá, Mory Kaba wí àwíjàre pé àwọn afẹ̀hónúhàn náà ń fẹ̀hónú hàn nítorí ṣíṣe àyẹ̀wò ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti àwọn ènìyàn láti lè gbégi Dínà ìtànkálẹ̀ àrùn Covid-19, ṣùgbọ́n àwọn afẹ̀hónúhàn náà takò wọ́n pè èyí kò rí bẹ́ẹ̀, wípé àwọn n ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn nítorí owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá náà ń gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.[12]

Ẹ yẹ̀yí wò

Àwọn Ìtọ́kasí