Àdùní Adé

Àdùní Adétí ó jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, àti módẹ́ẹ̀lì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n bí ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹfà ọdún 1976.[1][2]

Àdùní Adé(Adéwálé)
Adunni at the AMVCA 2020
Ọjọ́ìbíÀdùní Adéwálé
7 Oṣù Kẹfà 1976 (1976-06-07) (ọmọ ọdún 48)
Queens, New York, U.S.A.
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
American
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Kentucky
Iṣẹ́Actress, Model
Ìgbà iṣẹ́2006–present
Olólùfẹ́Nil
Àwọn ọmọ2

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀

Wọ́n bí Àdùní ní ìlú New York ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.[3] Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìlú Irish láti orílẹ̀-èdèGermany nígbà tí bàbá rẹ̀ jẹ́ Yorùbá ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[4] Wọ́n tọ́ Àdùní ní Ìpínlẹ̀ Èkó ati ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó àti Ìpínlẹ̀ Ògùn. Bàbá rẹ̀ fẹ́ràn aí kí ó kọ́ ìmọ̀ nípa ìṣirò owó ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Kentucky ní ọdún 2008.[5]

Iṣẹ́ rẹ̀

Adùní ti ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ mádàámi-dófò kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣáájú kí ó tó dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ eré ṣíse. Ó dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ módẹ́ẹ̀lì tí wọ́n gbé àsọ tuntun jáde. Ó kópa nínú ìdíje America's Next Top Model. Lẹ́yìn tí ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó kópa nínú eré àkọ́kọ́ rẹ̀ ní agbo Nollywood nínú eré Yorùbá kan tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní "You or I" ní ọdún 2013. Ó tún ti kópa nínú eré èdè Gẹ̀ẹ́sì àti ti Yorùbá. Ó ti kupa nínú fọ́ran àwo orin gbajú-gbajà olórin Sound Sultan àti Ice Prince kọ.[6][7]Àdùní ti gba amì-ẹ̀yẹ Stella Award ní ilé-iṣẹ́ Nigerian Institute of Journalism fún ipa rẹ̀ tí ó ń kó pélú bí ó ṣe ń gbé àṣà Yorùbá lárugẹ.[8] Ó di aṣojú fún ilé-iṣẹ́ OUD Majestic ní ọdún 2017.[9]

Ìgbé ayé rẹ̀

Àdùní ti bímọ méjì tí orúkọ wọn ń jẹ́ D'Marion àti Ayden.[10] Àdùní fi léde nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò kan wípé òun kò ní fẹ́ ọkọ mìíràn mọ́ lẹ́yìn ẹni akọ́kọ́ tí òun ti bímọ fún tí àwọn sì ti pín yà. [11][12][13]


Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

  • Iwo tabi emi (You or I) (2013)[14][15]
  • What's Within (2014)
  • 2nd Honeymoon (2014)
  • Head Gone (2015)
  • So in Love. (2015)
  • Schemers (2016)
  • Diary of a Lagos Girl (2016)
  • Diary of a Lagos girl (2016)
  • For The Wrong Reasons (2016)
  • It's Her Day (2016) Earned her the nomination for Best Supporting Actress in Africa's biggest Movie Awards, AMVCA in 2017. She also won Best Supporting Actress Award at the Lagos Film Festival for the movie.
  • The Blogger's Wife (2017)
  • Guyn Man (2017)
  • Boss of All Bosses (2018)
  • The Vendor (2018)
  • House Of Contention (2019)

Àwọn eré orí amóhù-máwòrán

  • Behind the Cloud
  • Babatunde Diaries
  • Jenifa's Diary Season 2
  • Sons of the caliphate Season 2

See also

  • List of Yoruba people

Àwọn Ìtọ́kasí

Àwọn ìjásóde

  • Àdàkọ:IMDb name

Àdàkọ:Authority control